life

OLUWA Ọlọrun si fi erupẹ ilẹ mọ enia; o si mí ẹmí ìye si ihò imu rẹ̀; enia si di alãye ọkàn.

JẸNẸSISI 2 : 7

O si wi fun Adamu pe, Nitoriti iwọ gbà ohùn aya rẹ gbọ́, ti iwọ si jẹ ninu eso igi na, ninu eyiti mo ti paṣẹ fun ọ pe, iwọ kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀; a fi ilẹ bú nitori rẹ; ni ipọnju ni iwọ o ma jẹ ninu rẹ̀ li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo;

JẸNẸSISI 3 : 17

OLUWA Ọlọrun si wipe, Wò o, ọkunrin na dabi ọkan ninu wa lati mọ̀ rere ati bururu: njẹ nisisiyi ki o má ba nà ọwọ́ rẹ̀ ki o si mu ninu eso igi ìye pẹlu, ki o si jẹ, ki o si yè titi lai;

JẸNẸSISI 3 : 22

OLUWA Ọlọrun si wi fun ejò na pe, nitori ti iwọ ti ṣe eyi, a fi iwọ bú ninu gbogbo ẹran ati ninu gbogbo ẹranko igbẹ; inu rẹ ni iwọ o ma fi wọ́, erupẹ ilẹ ni iwọ o ma jẹ li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo.

JẸNẸSISI 3 : 14

Ọlọrun si wipe, Ki omi ki o kún fun ọ̀pọlọpọ ẹdá alãye ti nrakò, ati ki ẹiyẹ ki o ma fò loke ilẹ li oju-ofurufu ọrun.

JẸNẸSISI 1 : 20

Li ẹgbẹta ọdún ọjọ́ aiye Noa, li oṣù keji, ni ọjọ́ kẹtadilogun oṣù, li ọjọ́ na ni gbogbo isun ibú nla ya, ati ferese iṣàn omi ọrun si ṣí silẹ.

JẸNẸSISI 7 : 11

Bẹ̃li o lé ọkunrin na jade; o si fi awọn kerubu ati idà ina dè ìha ìla-õrùn Edeni ti njù kakiri, lati ma ṣọ́ ọ̀na igi ìye na.

JẸNẸSISI 3 : 24

Lati inu ilẹ li OLUWA Ọlọrun mu onirũru igi hù jade wá, ti o dara ni wiwò, ti o si dara fun onjẹ; ìgi ìye pẹlu lãrin ọgbà na, ati igi ìmọ rere ati buburu.

JẸNẸSISI 2 : 9

Nitoripe ẹmi ara mbẹ ninu ẹ̀jẹ: emi si ti fi i fun nyin lati ma fi ṣètutu fun ọkàn nyin lori pẹpẹ nì: nitoripe ẹ̀jẹ ni iṣe ètutu fun ọkàn.

LEFITIKU 17 : 11

Emi pè ọrun ati ilẹ jẹri tì nyin li oni pe, emi fi ìye ati ikú, ibukún ati egún siwaju rẹ: nitorina yàn ìye, ki iwọ ki o le yè, iwọ ati irú-ọmọ rẹ:

DIUTARONOMI 30 : 19