friends

Irin a ma pọn irin: bẹ̃li ọkunrin ipọn oju ọrẹ́ rẹ̀.

ÌWÉ ÒWE 27 : 17

Máṣe ba onibinu enia ṣe ọrẹ́; má si ṣe ba ọkunrin oninu-fùfu rìn.

ÌWÉ ÒWE 22 : 24

Ẹniti o bò ẹ̀ṣẹ mọlẹ, o nwá ifẹ; ṣugbọn ẹniti o tun ọ̀ran hú silẹ, o yà ọrẹ́ nipa.

ÌWÉ ÒWE 17 : 9

Olododo tọ́ aladugbo rẹ̀ si ọ̀na; ṣugbọn ọ̀na awọn enia buburu tàn wọn jẹ.

ÌWÉ ÒWE 12 : 26

Ẹniti o ni ọrẹ́ pupọ, o ṣe e si iparun ara rẹ̀; ọrẹ́ kan si mbẹ ti o fi ara mọni ju arakunrin lọ.

ÌWÉ ÒWE 18 : 24

Kuro niwaju aṣiwere, ati lọdọ ẹniti kò ni ète ìmọ.

ÌWÉ ÒWE 14 : 7

Ororo ati turari mu ọkàn dùn: bẹ̃ni adùn ọrẹ ẹni nipa ìgbimọ atọkànwa.

ÌWÉ ÒWE 27 : 9

Ẹniti o mba ọlọgbọ́n rìn yio gbọ́n; ṣugbọn ẹgbẹ awọn aṣiwere ni yio ṣegbe.

ÌWÉ ÒWE 13 : 20

Nibiti malu kò si, ibujẹ a di ofo: ṣugbọn ibisi pupọ mbẹ nipa agbara malu.

ÌWÉ ÒWE 14 : 4

Fetisi ìmọ ki o si gbà ẹkọ́, ki iwọ ki o le gbọ́n ni igbẹhin rẹ.

ÌWÉ ÒWE 19 : 20