wisdom

Ayọ̀ ni wère fun ẹniti oye kù fun; ṣugbọn ẹni-oye a ma rìn ni iduroṣinṣin.

ÌWÉ ÒWE 15 : 21

Ibẹ̀ru Oluwa li ẹkọ́ ọgbọ́n; ati ṣãju ọlá ni irẹlẹ.

ÌWÉ ÒWE 15 : 33

Nigbati ọgbọ́n bá wọ̀ inu rẹ lọ, ti ìmọ si dùn mọ ọkàn rẹ;

ÌWÉ ÒWE 2 : 10

O to igbala jọ fun awọn olododo: on li asà fun awọn ti nrìn dede.

ÌWÉ ÒWE 2 : 7

Lati gbà ọ li ọwọ ẹni-ibi, li ọwọ ọkunrin ti nsọrọ ayidayida;

ÌWÉ ÒWE 2 : 12

Ọgbọ́n wà niwaju ẹniti o moye; ṣugbọn oju aṣiwère mbẹ li opin ilẹ̀-aiye.

ÌWÉ ÒWE 17 : 24

Bi ẹrín ni fun aṣiwere lati hu ìwa-ika: ṣugbọn ọlọgbọ́n li ẹni oye.

ÌWÉ ÒWE 10 : 23

Emi nrìn li ọ̀na ododo, larin ipa-ọ̀na idajọ:

ÌWÉ ÒWE 8 : 20

Lati gbà ọ li ọwọ ajeji obinrin, ani li ọwọ ajeji obinrin ti nfi ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ pọnni;

ÌWÉ ÒWE 2 : 16

A ti yàn mi lati aiyeraiye, lati ipilẹṣẹ, tabi ki aiye ki o to wà.

ÌWÉ ÒWE 8 : 23